Jagun Jagun

Akinkunmi Olagunju, Opeyemi Oyewande, Laolu Ajibade, Peter Sadibo, Olufemi Sanni, Babajide Okegbenro, Adegoke Odukoya, Ibrahim Oyetunji

[Chorus]
Jagun-jagun ló ń bọ̀
Jagun-jagun ló ń bọ̀
Jagun-jagun ló ń bọ̀

[Verse 1: Chant]
Olórí-ogun ò gbọdọ̀ kẹ́yìn ogun
Ọ̀kan ṣoṣo Ẹja tí ń d’abú-omi rú
Ọ̀kan ṣoṣo Ẹfọ̀n tí ń d’ọ̀dàn rú
Ọ̀kan ṣoṣo Àjànàkú tí ń m’igbó kìji-kìji
Jagun-jagun dé, ọmọ ọba kìí jagun bí ẹrú
Òlọ́ṣọmọ́dìí gba ìbọn lọ́wọ́ ọmọ ojo
Jagun-jagun, afiwájúgbọta, afẹ̀yìngbọfà
Jagun-jagun ò fẹ́rọ̀, alágbára èyàn tí ń fi májèlé ròfọ́
Àlùjànú èyàn tí ń fi ọmọ-odó tayín
Bó ṣe ń bá ọmọdé ṣe, bẹ́ẹ̀ ló ń bágbà ṣe
Kọ̀nàn-kọ̀nàn já tòun tòwú
Jagun-aso, ẹkùn ọkọ òkè!
Arọnimaja ṣáagun!
Ó ṣáagun ṣáagun, ó ṣáagun títí, ohun l’awo Alágbàá`a, èyí tí ó fi ta b’aṣeégún lójú

[Chorus]
Jagun-jagun ló ń bọ̀
Jagun-jagun ló ń bọ̀
Jagun-jagun ló ń bọ̀

Wissenswertes über das Lied Jagun Jagun von BANTU (Crew)

Wann wurde das Lied “Jagun Jagun” von BANTU (Crew) veröffentlicht?
Das Lied Jagun Jagun wurde im Jahr 2020, auf dem Album “Everybody Get Agenda” veröffentlicht.
Wer hat das Lied “Jagun Jagun” von BANTU (Crew) komponiert?
Das Lied “Jagun Jagun” von BANTU (Crew) wurde von Akinkunmi Olagunju, Opeyemi Oyewande, Laolu Ajibade, Peter Sadibo, Olufemi Sanni, Babajide Okegbenro, Adegoke Odukoya, Ibrahim Oyetunji komponiert.

Beliebteste Lieder von BANTU (Crew)

Andere Künstler von