Okunrin Meta (Edun Okan)
Gbémi ṣán lẹ̀
Kó mi sí'ta
Fàmí lẹ'wù ya
Tẹ̀mí lọ́rùn pa
Ènìyàn lásán ni mo jẹ́
Mo fú'yẹ́ bíi paper
Ìjí jà lódò
Ó gbémi lọ sóko
Ẹ̀dùn ọkàn
Òhun l'ọkọ̀
Gbé mi lọ síbi tó kàn
Ògá tà ògá ò tà
Ọlọ'ọ'pá gba rìbá kàsà
Ẹ̀dùn ọkàn
Òhun l'ọkọ̀
Gbé mi lọ ibi mò ń lọ
Ẹ̀dùn ọkàn
Fún mi lọ́kàn
Ọkùnrin mẹ́ta dé'bi tí mò ń lọ
Èmi ni ìmọ́lẹ̀
O ló'kùnkùn wọ gbó lọ
Mo fà á lẹ́'wù ya
Mo tẹ̀ l'ọ́rùn pa
Ènìyàn lásán mi ò jẹ́
Mo wíwo bí ẹ̀san
Èmi ni ìjì tó jà l'ódò
Tó gb'ọba wọn lọ s'óko
Ẹ̀dùn ọkàn
Òhun l'ọkọ̀
Gbé mi lọ síbi tó kàn
Ògá tà ògá ò tà
Ọlọ'ọ'pá gba rìbá kàsà
Ẹ̀dùn ọkàn
Òhun l'ọkọ̀
Gbé mi lọ ibi mò ń lọ
Ẹ̀dùn ọkàn
Fún mi lọ́kàn
Ọkùnrin mẹ́ta dé'bi tí mò ń lọ
Ẹ̀dùn ọkàn
Òhun l'ọkọ̀
Gbé mi lọ síbi tó kàn
Ògá tà ògá ò tà
Ọkùnrin mẹ́ta dé'bi tí mò n lọ